You can now download and listen to the audio of Ogbomoso Anthem or song (Orin Ogbomoso) here on My Woven Words. Just click the download button below.
- Ogbomoso Ajilete
Si ogo re l’a fe korin
Iwo t’a te s’arin odan
Okan ninu ilu Akin - A-to-sa-si n’jo t’o buru
Abo f’eniti eru mba
Odi t’ota ko le parun,
Ogun Filani ko ri mi - Oluwa olodumare
F’ow’otun re d’ilu wa mu
F’oba at’won ‘gbimo wa
L’emi at’ife ododo. - Kede re fun gbogbo eda
Egan ni “he” erin tobi
Ajanaku po, o ju ra
Ilu na l’ola gbangba ni - N’ijo ‘re elere ni iwa
B’ise ya, a se kangun ni
Omo Shoun fe ilu won
Ilu nwon ni Orisa nwon. - So f’awon wundia ti ndan
Fawon Okunrin rogbodo
E ho ye, e sape, e fo
Ilu ‘bukun! L’a bi nyin si - Awon Odo Ogbomoso
Yarin ‘ta re, ilu ti wa
Koto pelu gegele re
Igbo odan re l’ayo wa - Ki lo le mu wa gbagbe re
Ilu ‘Telorun at’ayo
Titi a o fi s’asunji
L’a o ma korin inyin re.
Composed by: Late Mr. D. Oladele Ajao
Former Senior Tutor, Baptist College, Iwo
(Harmony done by Rev A. B. Adeleke)
Ogbomoso Folk song
Ati de’nu Oko a sin mi o.
Ade’nu oko a simi
Ogun kan ko ja ja ja
Ko ko Ogbomoso ajilete
Ade’nu oko a simi
Note: The supposed “Ogbomoso Folk song” can be used as chorus for the stanzas in the anthem
Ogbomoso o
Ogbomoso o
Mo feran re
Ilu akoni
Ogbomoso o
Ogbomoso o
I love you
City of the brave


Thanks for visiting My Woven Words. We are passionate about historical heritage and we are dedicated to supplying nearly extinct historical and cultural contents to the world on a platter of gold.
Support us on our quest with Your donations by clicking the donate button below
DONATE
Ilu Ogbomoso ko ni baje ooo
weldone guys
ilu akoni
Thank you
I’m so proud of my hometown
Ilu Akoni
I’ve been searching everywhere for this, God bless you
Ogbomoso o ni baje o